Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀sùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlú u yín! Nítorí náà mo pe àpéjọ ńlá láti bá wọn wí.

Nehemiah 5:7 in English

Nehemiah 5:7 · Berean Standard Bible

and after serious thought I rebuked the nobles and officials, saying, “You are exacting usury from your own brothers!” So I called a large assembly against them

Context

5Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ ẹran-ara kan àti ẹ̀jẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ìlú wa tí àwọn ọmọkùnrin wa sì dára bí í tiwọn, síbẹ̀ àwa ní láti fi àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wa sí oko ẹrú. Díẹ̀ nínú àwọn ọmọbìnrin wa ti wà lóko ẹrú náà, ṣùgbọ́n àwa kò ní agbára, nítorí àwọn oko àti ọgbà àjàrà wa ti di ti ẹlòmíràn.” 6Èmi bínú gidigidi nígbà tí mo gbọ́ igbe wọn àti àwọn ẹ̀sùn wọ̀nyí. 7Mo rò wọ́n wò ní ọkàn mi mo sì fi ẹ̀sùn kan ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè. Mo sọ fún wọn pé, ẹ̀yin ń gba owó èlé lọ́wọ́ àwọn ará ìlú u yín! Nítorí náà mo pe àpéjọ ńlá láti bá wọn wí. 8Mo sì wí fún wọn pé, “Níbi tí àwa ní agbára mọ, àwa ti ra àwọn Júù arákùnrin wa tí a ti tà fún àwọn tí kì í ṣe Júù padà. Nísinsin yìí ẹ̀yìn ń ta àwọn arákùnrin yín, tí àwa sì tún ní láti rà wọ́n padà!” Wọ́n dákẹ́, nítorí wọn kò rí ohunkóhun sọ. 9Nítorí náà, mo tẹ̀síwájú pé, “Ohun tí ẹ̀ ń ṣe kò dára. Kò ha yẹ kí ẹ máa rìn nínú ìbẹ̀rù Ọlọ́run bí, láti yẹra fún ẹ̀gàn àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn tí í ṣe ọ̀tá wa?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.