Nehemiah 4:10
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Juda wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.”
Nehemiah 4:10 in English
Nehemiah 4:10 · Berean Standard Bible
Meanwhile, the people of Judah said:* “The strength of the laborer fails, and there is so much rubble that we will never be able to rebuild the wall.”
Context
8Gbogbo wọn jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti wá bá Jerusalẹmu jà àti láti dìde wàhálà sí í. 9Ṣùgbọ́n àwa gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan olùṣọ́ ọ̀sán àti ti òru láti kojú ìhàlẹ̀ yìí. 10Lákòókò yìí, àwọn ènìyàn Juda wí pé, “Agbára àwọn òṣìṣẹ́ ti dínkù, àlàpà púpọ̀ ni ó wà tó bẹ́ẹ̀ tí àwa kò fi le è mọ odi náà.” 11Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ọ̀tá wa wí pé, “Kí wọn tó mọ̀ tàbí kí wọn tó rí wa, àwa yóò ti dé àárín wọn, a ó sì pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.” 12Nígbà náà ni àwọn Júù tí ó ń gbé ní ẹ̀gbẹ́ wọn wá sọ fún wa ní ìgbà mẹ́wàá pé, “Ibikíbi tí ẹ̀yin bá padà sí, wọn yóò kọlù wá.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.