Nehemiah 3:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin Jeriko sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sakkuri ọmọ Imri sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ọkùnrin Jeriko.
Nehemiah 3:2 in English
Nehemiah 3:2 · Berean Standard Bible
The men of Jericho built next to Eliashib, and Zaccur son of Imri built next to them.
Context
1Eliaṣibu olórí àlùfáà àti àwọn àlùfáà arákùnrin rẹ̀ lọ ṣiṣẹ́, wọ́n sì tún ibodè Àgùntàn mọ. Wọ́n yà á sí mímọ́, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn dúró sí ibi tí ó yẹ, wọ́n mọ ọ́n títí dé ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn-ún, èyí tí wọ́n yà sí mímọ́ títí dé ilé ìṣọ́ gíga Hananeli. 2Àwọn ọkùnrin Jeriko sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sakkuri ọmọ Imri sì mọ ní ẹ̀gbẹ́ àwọn ọkùnrin Jeriko. 3Àwọn ọkùnrin Senaa ni wọ́n mọ ibodè ẹja. Wọ́n kún ọ̀pọ̀ ìgbéró rẹ̀, wọ́n sì gbé ìlẹ̀kùn rẹ̀, ìdábùú ìlẹ̀kùn àti àwọn ìdè e rẹ̀ sí ààyè e wọn. 4Meremoti ọmọ Uriah, ọmọ Hakosi tún èyí tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ ẹ wọn mọ. Ẹni tí ó tún wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ni Meṣullamu ọmọ Berekiah, ọmọ Meṣesabeli tún èyí ti ó wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn mọ. Bákan náà ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Sadoku ọmọ Baanah náà tún odi mọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.