Nehemiah 2:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?” Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run,
Nehemiah 2:4 in English
Nehemiah 2:4 · Berean Standard Bible
“What is your request?” replied the king. So I prayed to the God of heaven
Context
2Nítorí náà ni ọba béèrè lọ́wọ́ mi pé, “Èéṣe tí ojú rẹ fi fàro nígbà tí kò rẹ̀ ọ́? Èyí kì í ṣe ohun mìíràn bí kò ṣe ìbànújẹ́ ọkàn.”
Ẹ̀rù bà mí gidigidi, 3ṣùgbọ́n mo wí fún ọba pé, “Kí ọba kí ó pẹ́! Èéṣe tí ojú mi ko ṣe ní fàro, nígbà tí ìlú tí a sin àwọn baba mi sí wà ní ahoro, tí a sì ti fi iná run àwọn ibodè rẹ̀?” 4Ọba wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”
Nígbà náà, ni mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run, 5mo sì dá ọba lóhùn pé, “Ti ó bá wu ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì rí ojúrere ní ojú rẹ, jẹ́ kí ó rán mi lọ sí ìlú náà ní Juda níbi tí a sin àwọn baba mi nítorí kí èmi lè tún un kọ́.” 6Nígbà náà ni ọba, pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ tí ó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, bi mí pé, “Báwo ni ìrìnàjò náà yóò ṣe pẹ́ ọ tó, nígbà wo sì ni ìwọ yóò padà?” Ó dùn mọ́ ọba láti rán mi lọ, bẹ́ẹ̀ ni mo dá àkókò kan.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.