Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi. Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí.

Nehemiah 2:18 in English

Nehemiah 2:18 · Berean Standard Bible

I also told them about the gracious hand of my God upon me, and what the king had said to me. “Let us start rebuilding,” they replied, and they set their hands to this good work.

Context

16Àwọn olórí kò mọ ibi tí mo lọ tàbí mọ ohun tí mo ń ṣe, nítorí èmi kò tí ì sọ fún àwọn ará Júù tàbí àwọn àlùfáà tàbí àwọn ọlọ́lá tàbí àwọn ìjòyè tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn tí yóò máa ṣe iṣẹ́ náà. 17Nígbà náà ni mo sọ fún wọn pé, “Ṣé ẹ rí wàhálà tí a ni: Jerusalẹmu wà nínú ìparun, ibodè rẹ̀ ni a sì ti fi iná jó. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a tún odi Jerusalẹmu mọ, àwa kò sì ní jẹ́ ẹni ẹ̀gàn mọ́”. 18Èmi sì tún sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ àánú Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi àti ohun tí ọba ti sọ fún mi. Wọ́n dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a bẹ̀rẹ̀ àtúnmọ rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere yìí. 19Ṣùgbọ́n nígbà tí Sanballati ará a Horoni, Tobiah ara olóyè Ammoni àti Geṣemu ará a Arabia gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fi wá ṣe ẹlẹ́yà, wọ́n sì fi wá ṣe ẹ̀sín. Wọ́n béèrè pé, “Kí ni èyí tí ẹ ń ṣe yìí? Ṣé ẹ ń ṣọ̀tẹ̀ sí ọba ni?” 20Mo dá wọn lóhùn, mo wí fún wọn pé, “Ọlọ́run ọ̀run yóò fún wa ní àṣeyọrí. Àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò bẹ̀rẹ̀ láti tún un mọ, ṣùgbọ́n fún un yin, ẹ̀yin kò ní ìpín tàbí ipa tàbí ẹ̀tọ́ ohunkóhun tí ó jẹ mọ́ ìtàn ní Jerusalẹmu.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.