Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹmpili àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà.

Nehemiah 13:5 in English

Nehemiah 13:5 · Berean Standard Bible

and had prepared for Tobiah a large room where they had previously stored the grain offerings, the frankincense, the temple articles, and the tithes of grain, new wine, and oil prescribed for the Levites, singers, and gatekeepers, along with the contributions for the priests.

Context

3Nígbà tí àwọn ènìyàn gbọ́ òfin yìí, wọ́n yọ gbogbo àwọn àjèjì ènìyàn tí ó darapọ̀ mọ́ wọn kúrò láàrín àwọn Israẹli. 4Ṣáájú èyí a ti fi Eliaṣibu àlùfáà ṣe alákòóso yàrá ìkó nǹkan ilé Ọlọ́run wa sí. Ó súnmọ́ Tobiah pẹ́kípẹ́kí. 5Ó sì ti pèsè yàrá ńlá kan fún un, èyí tí a ń lò tẹ́lẹ̀ fún ìtọ́jú ọrẹ ọkà, tùràrí àti àwọn ohun èlò tẹmpili àti ìdámẹ́wàá ọkà, wáìnì tuntun àti òróró ti a fi lélẹ̀ bí ìlànà fún àwọn ọmọ Lefi, àwọn akọrin àti àwọn aṣọ́nà àti pẹ̀lú gbogbo ọrẹ fún àwọn àlùfáà. 6Ṣùgbọ́n nígbà tí gbogbo èyí ń lọ lọ́wọ́, èmi kò sí ní Jerusalẹmu, nítorí pé ní ọdún kejìlélọ́gbọ̀n Artasasta ọba Babeli ni mo padà tọ ọba lọ. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó ṣe díẹ̀, mo gba ààyè lọ́dọ̀ọ rẹ̀. 7Mo sì padà sí Jerusalẹmu. Níhìn-ín ni mo ti mọ̀ nípa onírúurú ohun búburú tí Eliaṣibu ti ṣe ní ti pípèsè yàrá fún Tobiah nínú àgbàlá ilé Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.