Nehemiah 13:24
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìdajì àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè Aṣdodu tàbí èdè ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mìíràn tókù, wọn kò sì mọ bí a ṣe ń sọ èdè Juda.
Nehemiah 13:24 in English
Nehemiah 13:24 · Berean Standard Bible
Half of their children spoke the language of Ashdod or of the other peoples, but could not speak the language of Judah.
Context
22Nígbà náà ni mo pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi pé kí wọn ya ara wọn sí mímọ́, kí wọn sì ṣọ́ ẹnu ibodè kí a lè pa ọjọ́ ìsinmi mọ́.
Tún rántí mi fún èyí, Ọlọ́run mi, kí o sì fi àánú un rẹ hàn fún mi gẹ́gẹ́ bí i títóbi ìfẹ́ ẹ̀ rẹ. 23Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, mo rí àwọn ọkùnrin Juda tí wọ́n fẹ́ àwọn obìnrin láti Aṣdodu, Ammoni àti Moabu. 24Ìdajì àwọn ọmọ wọn ń sọ èdè Aṣdodu tàbí èdè ọ̀kan lára àwọn ènìyàn mìíràn tókù, wọn kò sì mọ bí a ṣe ń sọ èdè Juda. 25Mo bá wọn wí mo sì gégùn ún lé wọn lórí. Mo lu àwọn ènìyàn díẹ̀ nínú wọn mo sì fa irun orí wọn tu. Mo mú kí wọn búra ní orúkọ Ọlọ́run, kí wọn wí pé, “Ẹ̀yin kì yóò fi àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó tàbí fún ẹ̀yin tìkára yín. 26Kì í ha á ṣe àwọn ìgbéyàwó bí irú èyí ni ọba Solomoni fi dá ẹ̀ṣẹ̀? Láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí ọba kan bí i tirẹ̀. Ọlọ́run rẹ̀ fẹ́ràn rẹ̀, Ọlọ́run sì fi jẹ ọba lórí i gbogbo Israẹli, ṣùgbọ́n àwọn obìnrin àjèjì ti sọ ọ́ sínú òfin ẹ̀ṣẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.