Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jerusalẹmu a mú àwọn ọmọ Lefi jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin kimbali, haapu àti ohun èlò orin olókùn.

Nehemiah 12:27 in English

Nehemiah 12:27 · Berean Standard Bible

At the dedication of the wall of Jerusalem, the Levites were sought out from all their homes and brought to Jerusalem to celebrate the joyous dedication with thanksgiving and singing, accompanied by cymbals, harps, and lyres.

Context

25Mattaniah, Bakbukiah, Obadiah, Meṣullamu, Talmoni àti Akkubu ni aṣọ́nà tí wọ́n ń sọ yàrá ìkó nǹkan pamọ́ sí ní ẹnu-ọ̀nà. 26Wọ́n ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ìgbà ayé e Joiakimu ọmọ Jeṣua, ọmọ Josadaki, àti ní ọjọ́ ọ Nehemiah baálẹ̀ àti ní ọjọ́ Esra àlùfáà àti akọ̀wé. 27Nígbà ìyàsímímọ́ odi Jerusalẹmu a mú àwọn ọmọ Lefi jáde wá láti ibi tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì mú wọn wá sí Jerusalẹmu láti fi ayọ̀ ṣe ayẹyẹ ìyàsímímọ́ pẹ̀lú orin ìdúpẹ́ àti pẹ̀lú ohun èlò orin kimbali, haapu àti ohun èlò orin olókùn. 28A kó àwọn akọrin náà jọ papọ̀ láti àwọn ìletò tí ó yí Jerusalẹmu náà ká—láti àwọn abúlé Netofa, 29láti Beti-Gilgali, àti láti àwọn agbègbè Geba àti Asmafeti, nítorí àwọn akọrin ti kọ́ àwọn ìletò fúnra wọn ní agbègbè Jerusalẹmu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.