Nehemiah 1:11
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olúwa, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sílẹ̀ sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ yìí, àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ní inú dídùn láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Fún ìránṣẹ́ rẹ ní àṣeyọrí lónìí kí o sì síjú àánú wò ó níwájú ọkùnrin yìí.” Nítorí tí mo jẹ́ agbọ́tí ọba nígbà náà.
Nehemiah 1:11 in English
Nehemiah 1:11 · Berean Standard Bible
O Lord, may Your ear be attentive to my prayer and to the prayers of Your servants * who delight to revere Your name. Give Your servant success this day, I pray, and grant him mercy in the sight of this man.” (At that time I was the cupbearer to the king.)
Context
9Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin bá yípadà sí mi, tí ẹ bá sì pa àṣẹ mi mọ́, nígbà náà bí àwọn ènìyàn yín tí a kó ní ìgbèkùn tilẹ̀ wà ní jìnnà réré ìpẹ̀kun ọ̀run, èmi yóò kó wọn jọ láti ibẹ̀, èmi yóò sì mú wọn wá, sí ibi tí èmi ti yàn bí i ibùgbé fún orúkọ mi.’ 10“Àwọn ni ìránṣẹ́ rẹ àti ènìyàn rẹ àwọn tí ìwọ rà padà pẹ̀lú agbára ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára ńlá rẹ. 11Olúwa, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sílẹ̀ sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ yìí, àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí wọ́n ní inú dídùn láti bọ̀wọ̀ fún orúkọ rẹ. Fún ìránṣẹ́ rẹ ní àṣeyọrí lónìí kí o sì síjú àánú wò ó níwájú ọkùnrin yìí.”
Nítorí tí mo jẹ́ agbọ́tí ọba nígbà náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.