Native Bible

Mark 9:30 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Galili kọjá. Níbẹ̀ ni Jesu ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i.

Mark 9:30 in English

Mark 9:30 · Berean Standard Bible

Going on from there, they passed through Galilee. But Jesus did not want anyone to know,

Context

28Nígbà tí ó sì wọ ilé, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ bi í léèrè níkọ̀kọ̀ wí pé, “Èéṣe tí àwa kò fi lè lé e jáde?” 29Ó sì wí fún wọn pé, “Irú èyí kò le ti ipa ohun kan jáde, bí kò ṣe nípa àdúrà.”* 30Wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọ́n gba Galili kọjá. Níbẹ̀ ni Jesu ti gbìyànjú láti yẹra kí ó bá à lè wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, kí ó lè ráàyè kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ sí i. 31Nítorí ó kọ́ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì wí fun wọn pe, “A ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́, wọn ó sì pa á, lẹ́yìn ìgbà tí a bá sì pa á tan yóò jíǹde ní ọjọ́ kẹta.” 32Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ẹ̀rù sì bà wọ́n láti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ìtumọ̀ ohun tí ó sọ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.