Native Bible

Mark 8:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mí pè?” Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.”

Mark 8:29 in English

Mark 8:29 · Berean Standard Bible

“But what about you?” Jesus asked. “Who do you say I am?” Peter answered, “You are the Christ.”

Context

27Nísinsin yìí, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kúrò ní Galili. Wọ́n sì jáde lọ sí àwọn abúlé ní agbègbè Kesarea-Filipi. Bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi mí pè?” 28Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà dáhùn pé, “Àwọn kan rò pé ìwọ ni Johanu Onítẹ̀bọmi, àwọn mìíràn sọ pé, ìwọ ni Elijah tàbí àwọn wòlíì mìíràn ni ó tún padà wá sáyé.” 29Ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fi mí pè?” Peteru dáhùn pé, “Ìwọ ni Kristi náà.” 30Ṣùgbọ́n Jesu kìlọ̀ fún wọn, kí wọn má sọ èyí fún ẹnikẹ́ni. 31Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn, pé, Ọmọ Ènìyàn kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀ láti ọwọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin, a ó sì pa á, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò sì jíǹde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.