Native Bible

Mark 8:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?” Wọ́n wí pé, “Méjìlá.”

Mark 8:19 in English

Mark 8:19 · Berean Standard Bible

When I broke the five loaves for the five thousand, how many basketfuls of broken pieces did you collect?” “Twelve,” they answered.

Context

17Jesu mọ ohun tí wọ́n sọ láàrín ara wọn, ó sì dá wọn lóhùn pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe àròyé pé ẹ̀yin kò mú àkàrà lọ́wọ́? Ẹ̀yin kò kíyèsi i títí di ìsinsin yìí, ẹ kò sì ti mòye, àbí ọkàn yín le ni. 18Ẹ̀yin ní ojú, ẹ kò fi ríran? Ẹ̀yin ni etí ẹ kò sí gbọ́ran? Ẹ̀yin kò sì rántí? 19Nígbà ti mo bu ìṣù àkàrà márùn-ún fún ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn, agbọ̀n mélòó ni ó kún fún àjẹkù tí ẹ ṣàjọ?” Wọ́n wí pé, “Méjìlá.” 20“Bákan náà, nígbà tí mo bọ́ ẹgbàajì (4,000) pẹ̀lú ìṣù àkàrà méje, agbọ̀n mélòó ló kù sílẹ̀ lẹ́yìn àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn wọn?” Wọ́n dáhùn pé, “Ó ku ẹ̀kún agbọ̀n méje.” 21Ó sì wí fún wọn pé, “Èéha ti ṣe tí kò fi yé yin?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.