Marku 7:4
Mark 7:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.)
Mark 7:4 in English
Mark 7:4 · Berean Standard Bible
And on returning from the market, they do not eat unless they wash. And there are many other traditions for them to observe, including the washing of cups, pitchers, kettles, and couches for dining.*
Context
2wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́. 3(Àwọn Farisi, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kì í jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́. 4Nígbà tí wọ́n bá sì ti ọjà dé sílé, wọn kò gbọdọ̀ fi ọwọ́ kan oúnjẹ àfi tí wọ́n bá bu omi wẹ ara wọn. Èyí sì jẹ́ ọ̀kan nínú ogunlọ́gọ̀ àpẹẹrẹ òfin àti ìlànà tí wọ́n ti dì mú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí i fífọ kọ́ọ̀bù, àwọn ìkòkò, àti kẹ́tù.) 5Nítorí èyí àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kò tẹ̀lé àwọn òfin àtọwọ́dọ́wọ́ àwọn àgbà nítorí wọ́n fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun?” 6Jesu dá wọn lóhùn wí pé, “Ẹyin àgàbàgebè yìí, òtítọ́ ni wòlíì Isaiah ń sọtẹ́lẹ̀ nípa tí ẹ̀yin àgàbàgebè, bí a ti kọ ọ́ pé:
“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí fi ẹnu wọn bu ọlá fún mi
ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnà sí mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.