Marku 7:24
Mark 7:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri.
Mark 7:24 in English
Mark 7:24 · Berean Standard Bible
Jesus left that place and went to the region of Tyre.* Not wanting anyone to know He was there, He entered a house, but was unable to escape their notice.
Context
22ọ̀kánjúwà, odì yíyàn, ìtànjẹ, ìmọ-tara-ẹni, ìlara, ọ̀rọ̀ ẹ̀yìn, ìgbéraga, òmùgọ̀. 23Gbogbo àwọn nǹkan búburú wọ̀nyí ń tí inú wá, àwọn ló sì ń sọ yín di aláìmọ́.” 24Nígbà náà ni Jesu kúrò ní Galili, ó sí lọ sí agbègbè Tire àti Sidoni, ó sì gbìyànjú láti nìkan wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ fún àkókò díẹ̀, ṣùgbọ́n eléyìí kò ṣe é ṣe, nítorí pé kò pẹ́ púpọ̀ tí ó wọ ìlú nígbà tí ìròyìn dídé rẹ̀ tàn káàkiri. 25Láìpẹ́, obìnrin kan tí ọmọbìnrin rẹ̀ ní ẹ̀mí àìmọ́ tọ̀ ọ́ wá, ó ti gbọ́ nípa Jesu, ó wá, ó sì wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu. 26Giriki ní obìnrin náà, Siro-Fonisia ní orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ó bẹ Jesu kí ó bá òun lé ẹ̀mí èṣù náà jáde lára ọmọbìnrin òun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.