Native Bible

Mark 4:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n sì gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Àwọn ọkọ̀ ojú omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀.

Mark 4:36 in English

Mark 4:36 · Berean Standard Bible

After they had dismissed the crowd, they took Jesus with them, since He was already in the boat. And there were other boats with Him.

Context

34Kìkì òwe ni Jesu fi ń kọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́ ìta gbangba rẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn èyí, nígbà tí ó bá sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, òun a sì sọ ìtumọ̀ ohun gbogbo. 35Nígbà tí alẹ́ lẹ́, Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jẹ́ kí a rékọjá sí apá kejì.” 36Nígbà tí wọn ti tú ìjọ ká, wọ́n sì gbà á sínú ọkọ̀ ojú omi gẹ́gẹ́ bí ó ti wà. Àwọn ọkọ̀ ojú omi kékeré mìíràn sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀. 37Ìjì líle ńlá kan sì dìde, omi sì ń bù sínú ọkọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ọkọ̀ fi bẹ̀rẹ̀ sí í kún fún omi, ó sì fẹ́rẹ rì. 38Jesu ti sùn lọ lẹ́yìn ọkọ̀, ó gbé orí lé ìrọ̀rí. Wọ́n sì jí i lóhùn rara wí pé, “Olùkọ́ni, tàbí ìwọ kò tilẹ̀ bìkítà pé gbogbo wa fẹ́ rì?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.