Marku 4:31
Mark 4:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀.
Mark 4:31 in English
Mark 4:31 · Berean Standard Bible
It is like a mustard seed, which is the smallest of all seeds sown upon the earth.
Context
29Nígbà tí èso bá gbó tán, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun a tẹ dòjé bọ inú ọkà náà, ó sì kórè rẹ̀.” 30Jesu sì tún wí pé, “Kí ni kí èmi fi ìjọba Ọlọ́run wé? Òwe wo ni kí èmi fi ṣe àkàwé rẹ̀? 31Ó dàbí èso hóró musitadi kan, lóòótọ́, ó jọ ọ̀kan nínú àwọn èso tí ó kéré jùlọ ti a gbìn sínú ilẹ̀. 32Síbẹ̀, nígbà tí a gbìn ín, ó dàgbàsókè, ó gbilẹ̀, ó sì di títóbi ju gbogbo ewéko inú ọgbà yòókù lọ. Ó sì yọ ẹ̀ka ńlá níbi tí àwọn ẹyẹ ọ̀run lè kọ́ ìtẹ́ wọn sí, kí wọn sì rí ìdáàbòbò.” 33Òun lo ọ̀pọ̀ irú òwe wọ̀nyí láti fi kọ́ àwọn ènìyàn, gẹ́gẹ́ bí wọ́n bá ti ń fẹ́ láti ní òye tó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.