Marku 3:7
Mark 3:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili àti Judea sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Mark 3:7 in English
Mark 3:7 · Berean Standard Bible
So Jesus withdrew with His disciples to the sea, accompanied by a large crowd from Galilee, Judea,
Context
5Nígbà tí ó sì wo gbogbo wọn yíká pẹ̀lú ìbínú, ọkàn rẹ̀ sì bàjẹ́ nítorí líle àyà wọn, ó sọ fún ọkùnrin náà pé, “Na ọwọ́ rẹ jáde.” Ó nà án jáde, ọwọ́ náà sì bọ̀ sípò padà pátápátá. 6Lójúkan náà, àwọn Farisi jáde lọ, láti bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Herodu gbìmọ̀ pọ̀, bí wọn yóò ṣe pa Jesu. 7Jesu pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra kúrò níbẹ̀ lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn láti Galili àti Judea sì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. 8Nígbà tí wọ́n gbọ́ ìròyìn iṣẹ́ ìyanu tí ó ṣe, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá láti Judea, Jerusalẹmu àti Idumea, àti láti apá kejì odò Jordani àti láti ìhà Tire àti Sidoni. 9Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, Jesu sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti ṣètò ọkọ̀ ojú omi kékeré kan sílẹ̀ fún un láti lọ, láti lé àwọn èrò sẹ́yìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.