Native Bible

Mark 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé.

Mark 2:3 in English

Mark 2:3 · Berean Standard Bible

Then a paralytic was brought to Him, carried by four men.

Context

1Lẹ́yìn ọjọ́ mélòó kan, nígbà tí Jesu tún padà wọ Kapernaumu, òkìkí kàn pé ó ti wà nínú ilé. 2Láìpẹ́, ogunlọ́gọ̀ ènìyàn ti kún ilé tí ó dé sí tó bẹ́ẹ̀ tí inú ilé àti ẹ̀yìn ìlẹ̀kùn ní ìta kò gba ẹyọ ẹnìkan mọ́, ó sì wàásù ọ̀rọ̀ náà sí wọn. 3Àwọn ọkùnrin kan wá, wọ́n gbé arọ tọ̀ ọ́ wá, ẹni tí ọkùnrin mẹ́rin gbé. 4Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jesu, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jesu wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti àkéte rẹ̀ níwájú Jesu. 5Nígbà tí Jesu sì rí ìgbàgbọ́ wọn, ó sọ fún arọ náà pé, “Ọmọ, a dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.