Marku 2:15
Mark 2:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì ṣe, bí ó sì ti jókòó ti oúnjẹ ni ilé Lefi, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jesu jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí tiwọn pọ̀ tiwọn tẹ̀lé e.
Mark 2:15 in English
Mark 2:15 · Berean Standard Bible
While Jesus was dining at Levi’s house, many tax collectors and sinners were eating with Him and His disciples—for there were many who followed Him.
Context
13Nígbà náà, Jesu tún jáde lọ sí etí Òkun. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì tọ̀ ọ́ wá, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ wọn. 14Bí ó ti ń rin etí Òkun lọ sókè, ó rí Lefi ọmọ Alfeu tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jesu sì wí fún un pé, “Tẹ̀lé mi,” Lefi dìde, ó sì ń tẹ̀lé e. 15Ó sì ṣe, bí ó sì ti jókòó ti oúnjẹ ni ilé Lefi, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jesu jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí tiwọn pọ̀ tiwọn tẹ̀lé e. 16Nígbà tí àwọn olùkọ́ òfin àti àwọn Farisi rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Èétirí tí ó fi ń bá àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?” 17Nígbà tí Jesu gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá láti sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.