Native Bible

Mark 16:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Peteru wí pé, ‘Òun ti ń lọ síwájú yín sí Galili. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ”

Mark 16:7 in English

Mark 16:7 · Berean Standard Bible

But go, tell His disciples and Peter, ‘He is going ahead of you into Galilee. There you will see Him, just as He told you.’”

Context

5Nígbà tí wọ́n sì wo inú ibojì náà, wọ́n rí ọ̀dọ́mọkùnrin kàn tí ó wọ aṣọ funfun, ó jókòó ní apá ọ̀tún, ẹnu sì yà wọn. 6Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má bẹ̀rù: ẹ̀yin ń wá Jesu tí Nasareti, tí a kàn mọ́ àgbélébùú. Ó jíǹde! Kò sí níhìn-ín yìí mọ́, ẹ wo ibi tí wọ́n gbé tẹ́ ẹ sí. 7Ṣùgbọ́n ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ títí kan Peteru wí pé, ‘Òun ti ń lọ síwájú yín sí Galili. Ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò ti rí i, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ fún yín.’ ” 8Wọ́n sáré jáde lọ kánkán, kúrò ní ibi ibojì náà, nítorí tí wọ́n wárìrì; ẹ̀rù sì bà wọn gidigidi; wọn kò wí ohunkóhun fún ẹnikẹ́ni, nítorí ẹ̀rù bá wọ́n. 9Nígbà tí Jesu jíǹde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ní ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fi ara hàn fun Maria Magdalene, ni ara ẹni tí ó ti lé ẹ̀mí Èṣù méje jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.