Native Bible

Mark 15:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pilatu, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún.

Mark 15:8 in English

Mark 15:8 · Berean Standard Bible

So the crowd went up and began asking Pilate to keep his custom.

Context

6Ní báyìí, nígbà àjọ, gẹ́gẹ́ bí àṣà, òun a máa dá òǹdè kan sílẹ̀ fún wọn, ẹnikẹ́ni tí wọ́n bá béèrè fún. 7Ọkùnrin kan wà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Baraba. Wọ́n ti ju òun àti àwọn ọlọ̀tẹ̀ ẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, nítorí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí ìjọba, wọ́n sì pa ènìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn. 8Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì lọ bá Pilatu, wọ́n ní kí ó ṣe bí ó ti máa ń ṣe fún wọn ní ọdọọdún. 9Pilatu béèrè lọ́wọ́ wọn wí pé, “Ṣe ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi dá ọba àwọn Júù sílẹ̀ fún yin?” 10Òun mọ̀ pé nítorí ìlara ni àwọn olórí àlùfáà ṣe fà Jesu lé òun lọ́wọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.