Marku 15:32
Mark 15:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀.
Mark 15:32 in English
Mark 15:32 · Berean Standard Bible
Let the Christ, the King of Israel, come down now from the cross, so that we may see and believe!” And even those who were crucified with Him berated Him.
Context
30sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú wá, kí o sì gba ara rẹ là!” 31Bákan náà ni àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin fi í ṣẹ̀sín láàrín ara wọn, wọ́n wí pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là ṣùgbọ́n, ara rẹ̀ ni kò lè gbàlà. 32Jẹ́ kí Kristi, ọba Israẹli, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú wá nísinsin yìí kí àwa kí ó lè rí i, kí àwa kí ó sì lè gbàgbọ́.” Bákan náà, àwọn ti a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀ sì ń kẹ́gàn rẹ̀. 33Nígbà tí ó di wákàtí kẹfà, òkùnkùn bo gbogbo ilẹ̀ títí di wákàtí kẹsànán. 34Ní wákàtí kẹsànán ni Jesu kígbe sókè ní ohùn rara, ó ní, “Eli, Eli, lama sabakitani?” (ìtumọ̀ èyí tí í ṣe, “Ọlọ́run mi, Ọlọ́run mi, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí sílẹ̀?”).
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.