Native Bible

Mark 15:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú ààfin (tí a ń pè ní Pretoriomu), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ogun jọ.

Mark 15:16 in English

Mark 15:16 · Berean Standard Bible

Then the soldiers led Jesus away into the palace (that is, the Praetorium) and called the whole company together.

Context

14Nígbà náà ni Pilatu bi wọn léèrè pé, “Èéṣe? Búburú kí ni ó ṣe?” Wọ́n sì kígbe sókè gidigidi wí pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!” 15Pilatu sì ń fẹ́ ṣe èyí tí ó wu àwọn ènìyàn, ó dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Nígbà tí ó sì na Jesu tan o fà á lé wọn lọ́wọ́ láti kàn an mọ́ àgbélébùú. 16Àwọn ọmọ-ogun sì fà á jáde lọ sínú ààfin (tí a ń pè ní Pretoriomu), wọ́n sì pe gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ọmọ-ogun jọ. 17Wọn sì fi aṣọ aláwọ̀ àlùkò wọ̀ ọ́, wọ́n hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí. 18Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí i kí ì wí pé, Kábíyèsí, ọba àwọn Júù.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.