Native Bible

Mark 14:54 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Peteru tẹ̀lé Jesu lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná.

Mark 14:54 in English

Mark 14:54 · Berean Standard Bible

Peter followed Him at a distance, right into the courtyard of the high priest. And he sat with the officers and warmed himself by the fire.

Context

52Ó sì fi aṣọ funfun náà sílẹ̀ fún wọn, ó sì sálọ ní ìhòhò. 53Wọ́n mú Jesu lọ sí ilé olórí àlùfáà, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù àti àwọn olùkọ́ òfin péjọ síbẹ̀. 54Peteru tẹ̀lé Jesu lókèèrè, ó sì yọ́ wọ inú àgbàlá olórí àlùfáà, ó sì jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ó ń yáná. 55Bí ó ti ń ṣe èyí lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti gbogbo ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ tí ó ga jùlọ ń wá ẹni tí yóò jẹ́rìí èké sí Jesu, èyí tí ó jọjú dáradára láti lè dájọ́ ikú fún un. Ṣùgbọ́n wọn kò rí. 56Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀rí wọ́n ní kò bá ara wọn mu.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.