Native Bible

Mark 14:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni.

Mark 14:20 in English

Mark 14:20 · Berean Standard Bible

He answered, “It is one of the Twelve—the one who is dipping his hand * into the bowl with Me.

Context

18Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.” 19Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?” 20Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni. 21Nítòótọ́ Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.” 22Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.