Marku 13:5
Mark 13:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín.
Mark 13:5 in English
Mark 13:5 · Berean Standard Bible
Jesus began by telling them, “See to it that no one deceives you.
Context
3Bí Jesu si ti jókòó lórí òkè olifi tí ó kọjú sí tẹmpili, Peteru, Jakọbu, Johanu àti Anderu wà pẹ̀lú rẹ̀ níbẹ̀, wọ́n bi í léèrè ni ìkọ̀kọ̀ pé, 4“Sọ fún wa, nígbà wo ni nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹlẹ̀ sí tẹmpili náà? Kí ni yóò sì jẹ́ àmì nígbà tí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò ṣẹ?” 5Jesu kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tàn yín. 6Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò wá ní orúkọ mi, wọn yóò wí pé, ‘Èmi ni Kristi,’ wọn yóò tan ọ̀pọ̀ ènìyàn jẹ. 7Nígbà tí ẹ̀yin bá ń gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má ṣe jáyà, nítorí irú nǹkan wọ̀nyí kò le ṣe kí ó má ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin náà kì í ṣe ìgbà yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.