Native Bible

Mark 13:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn.

Mark 13:12 in English

Mark 13:12 · Berean Standard Bible

Brother will betray brother to death, and a father his child. Children will rise against their parents and have them put to death.

Context

10Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìyìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. 11Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́. 12“Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn. 13Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà. 14“Ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á kí ó yé e), nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.