Native Bible

Mark 12:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.

Mark 12:42 in English

Mark 12:42 · Berean Standard Bible

Then one poor widow came and put in two small copper coins, which amounted to a small fraction of a denarius.*

Context

40Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.” 41Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. 42Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀. 43Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. 44Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.