Marku 12:39
Mark 12:39 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè.
Mark 12:39 in English
Mark 12:39 · Berean Standard Bible
and to have the chief seats in the synagogues and the places of honor at banquets.
Context
37Níwọ́n ìgbà tí Dafidi tìkára rẹ̀ pè é ní ‘Olúwa,’ báwo ni ó túnṣe lè jẹ́ ọmọ rẹ̀?”
Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì fi ayọ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 38Ó sì wí fún wọn nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣọ́ra fun àwọn olùkọ́ òfin tí wọ́n fẹ́ láti máa wọ aṣọ gígùn káàkiri, tí wọ́n sì fẹ́ ìkíni ní ọjà, 39àti ibùjókòó ọlá nínú Sinagọgu àti ipò ọlá níbi àsè. 40Àwọn tí wọ́n jẹ ilé àwọn opó rún, tí wọ́n sì ń gbàdúrà gígùn fún àṣehàn, nítorí èyí, ìjìyà wọn yóò pọ̀ púpọ̀.” 41Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.