Native Bible

Mark 12:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.”

Mark 12:33 in English

Mark 12:33 · Berean Standard Bible

and to love Him with all your heart and with all your understanding and with all your strength, and to love your neighbor as yourself, which is more important than all burnt offerings and sacrifices.”

Context

31Èkejì ni pé: ‘Fẹ́ ọmọnìkejì rẹ.’ Kò sí òfin mìíràn tó ga ju méjèèjì yìí lọ.” 32Olùkọ́ òfin náà dáhùn pé, “Olùkọ́, ìwọ sọ òtítọ́ nípa pé Ọlọ́run kan ni ó ń bẹ, àti pé kò sí òmíràn àfi òun nìkan. 33Àti kí a fi gbogbo àyà, àti gbogbo òye, àti gbogbo ọkàn àti gbogbo agbára fẹ́ ẹ, àti fẹ́ ọmọnìkejì ẹni bí ara ẹni, ó ju gbogbo ẹbọ sísun, àti ẹbọ lọ.” 34Jesu rí i dájú pé òye ọkùnrin yìí ga, nítorí náà, Jesu sọ fún un pé, “Arákùnrin, ìwọ kò jìnà sí à ti dé ìjọba Ọ̀run.” Láti ìgbà náà lọ, ẹnikẹ́ni kò tún béèrè ohun kan lọ́wọ́ Jesu. 35Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jesu ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú tẹmpili, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èéṣe tí àwọn olùkọ́ òfin fi gbà wí pé Kristi náà ní láti jẹ́ ọmọ Dafidi?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.