Marku 12:17
Mark 12:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.” Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀.
Mark 12:17 in English
Mark 12:17 · Berean Standard Bible
Then Jesus told them, “Give to Caesar what is Caesar’s, and to God what is God’s.” And they marveled at Him.
Context
15Kí àwa kí ó fi fún un, tàbí kí a máa fi fún un?
Ṣùgbọ́n Jesu mọ ìwà àgàbàgebè wọn. Ó sì wí pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi n fi èyí dán mi wo? Ẹ mú owó idẹ kan wá kí n wò ó.” 16Nígbà tí wọ́n mú owó idẹ náà fún un, ó bi wọ́n léèrè pé, “Ẹ wò ó! Àwòrán àti orúkọ ta ni ó wà níbẹ̀?”
Wọ́n dáhùn pé, “Àwòrán àti orúkọ Kesari ni.” 17Nígbà náà ni Jesu wí fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó bá jẹ́ ti Kesari fún Kesari. Ṣùgbọ́n ẹ fi ohun gbogbo tí í ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”
Ẹnu sì yà wọ́n gidigidi sí èsì rẹ̀. 18Àwọn Sadusi tún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn wọ̀nyí kò gbàgbọ́ pé àjíǹde ń bẹ. Ìbéèrè wọn ni pé, 19“Olùkọ́, Mose fún wa ní òfin pé, nígbà tí ọkùnrin kan bá kú láìbí ọmọ, arákùnrin rẹ̀ gbọdọ̀ ṣú ìyàwó náà lópó kí wọn sì bímọ ní orúkọ ọkọ tí ó kú náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.