Marku 10:32
Mark 10:32 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nísinsin yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerusalẹmu. Jesu sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn. Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn.
Mark 10:32 in English
Mark 10:32 · Berean Standard Bible
As they were going up the road to Jerusalem, Jesus was walking ahead of them. The disciples were amazed, but those who followed were afraid. Again Jesus took the Twelve aside and began to tell them what was going to happen to Him:
Context
30tí a kì yóò fún padà ní ọgọọgọ́rùn-ún àwọn ilé, tàbí arákùnrin, tàbí arábìnrin, tàbí ìyá, tàbí ọmọ, tàbí ilẹ̀, àti inúnibíni pẹ̀lú. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò jẹ́ tirẹ̀ ní ayé yìí àti pé ní ayé tó ń bọ̀ yóò ní ìyè àìnípẹ̀kun. 31Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn tí ó síwájú ni yóò di ẹni ìkẹyìn, àwọn tí ó sì kẹ́yìn yóò síwájú.” 32Nísinsin yìí, wọ́n wà lójú ọ̀nà sí Jerusalẹmu. Jesu sì ń lọ níwájú wọn, bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti ń tẹ̀lé e, ìbẹ̀rù kún ọkàn wọn. Ó sì tún mú àwọn méjìlá sí apá kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé ohun gbogbo tí a ó ṣe sí i fún wọn. 33Ó sọ fún wọn pé, “Àwa ń gòkè lọ Jerusalẹmu, a ó sì fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́. Wọn ni yóò dá lẹ́bi ikú. Wọn yóò sì fà á lé ọwọ́ àwọn aláìkọlà. 34Wọn yóò fi ṣe ẹlẹ́yà, wọn yóò tutọ́ sí ní ara, wọn yóò nà pẹ̀lú pàṣán wọn. Wọn yóò sì pa, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta yóò tún jíǹde.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.