Native Bible

Mark 1:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un.

Mark 1:13 in English

Mark 1:13 · Berean Standard Bible

and He was there for forty days, being tempted by Satan. He was with the wild animals, and the angels ministered to Him.

Context

11Ohùn kan sì ti ọ̀run wá wí pé, “Ìwọ ni àyànfẹ́ Ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” 12Lẹ́sẹ̀kan náà, Ẹ̀mí Mímọ́ sì darí Jesu sí ijù, 13Ó sì wà ní ogójì ọjọ́ ní aginjù. A sì ti ọwọ́ Satani dán an wò, ó sì wà pẹ̀lú àwọn ẹranko ìgbẹ́. Àwọn angẹli sì ń ṣe ìránṣẹ́ fún un. 14Lẹ́yìn ìgbà tí ọba Herodu ti fi Johanu sínú ẹ̀wọ̀n tan, Jesu lọ sí Galili, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run. 15Ó sì kéde wí pé, “Àkókò náà dé wàyí, ìjọba Ọlọ́run kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹ yípadà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì gba ìyìnrere yìí gbọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.