Matiu 9:7
Matthew 9:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀.
Matthew 9:7 in English
Matthew 9:7 · Berean Standard Bible
And the man got up and went home.
Context
5Èwo ni ó rọrùn jù: láti wí pé, ‘A dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ jì ọ,’ tàbí wí pé, ‘Dìde, kí o sì máa rìn?’ 6Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé Ọmọ Ènìyàn ní agbára ní ayé láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì ni.” Ó sì wí fún arọ náà pé, “Dìde, sì gbé àkéte rẹ, kí o sì máa lọ ilé rẹ.” 7Ọkùnrin náà sì dìde, ó sì lọ ilé rẹ̀. 8Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn. 9Bí Jesu sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrin kan ti à ń pè ní Matiu, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Matiu sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.