Native Bible

Matthew 8:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run.

Matthew 8:11 in English

Matthew 8:11 · Berean Standard Bible

I say to you that many will come from the east and the west to share the banquet with Abraham, Isaac, and Jacob in the kingdom of heaven.

Context

9Ẹni tí ó wà lábẹ́ àṣẹ sá ni èmi, èmi sí ní ọmọ-ogun lẹ́yìn mi. Bí mo wí fún ẹni kan pé, ‘Lọ,’ a sì lọ, àti fún ẹni kejì pé, ‘Wá,’ a sì wá, àti fún ọmọ ọ̀dọ̀ mi pé, ‘Ṣe èyí,’ a sì ṣe é.” 10Nígbà tí Jesu gbọ́ èyí ẹnu yà á, ó sì wí fún àwọn tí ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, èmi kò rí ẹnìkan ni Israẹli tó ní ìgbàgbọ́ ńlá bí irú èyí. 11Mo sì wí fún yín, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò ti ìhà ìlà-oòrùn àti ìhà ìwọ̀-oòrùn wá, wọ́n á sì bá Abrahamu àti Isaaki àti Jakọbu jẹun ní ìjọba ọ̀run. 12Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ìjọba ni a ó sọ sínú òkùnkùn lóde, níbẹ̀ ni ẹkún àti ìpayínkeke yóò gbé wà.” 13Nítorí náà Jesu sì wí fún balógun ọ̀run náà pé, “Máa lọ ilé, ohun tí ìwọ gbàgbọ́ ti rí bẹ́ẹ̀.” A sì mú ọmọ ọ̀dọ̀ náà láradá ní wákàtí kan náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.