Native Bible

Matthew 6:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’

Matthew 6:31 in English

Matthew 6:31 · Berean Standard Bible

Therefore do not worry, saying, ‘What shall we eat?’ or ‘What shall we drink?’ or ‘What shall we wear?’

Context

29Bẹ́ẹ̀ ni mo wí fún yín pé, a kò ṣe Solomoni lọ́ṣọ̀ọ́ nínú gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí. 30Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ bẹ́ẹ̀, èyí tí ó wà níhìn-ín lónìí ti a sì gbà sínú iná lọ́la, kò ha ṣe ni ṣe yín lọ́ṣọ̀ọ́ tó bẹ́ẹ̀ àti jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ̀yin tí ìgbàgbọ́ yín kéré? 31Nítorí náà, ẹ má ṣe ṣe àníyàn kí ẹ sì máa wí pé, ‘Kí ni àwa yóò jẹ?’ tàbí ‘Kí ni àwa yóò mu?’ tàbí ‘Irú aṣọ wo ni àwa yóò wọ̀?’ 32Nítorí àwọn kèfèrí ń fi ìwọra wá àwọn nǹkan wọ̀nyí bẹ́ẹ̀ ni Baba yín ní ọ̀run mọ̀ dájúdájú pé ẹ ní ìlò àwọn nǹkan wọ̀nyí. 33Ṣùgbọ́n, ẹ kọ́kọ́ wá ìjọba Ọlọ́run ná àti òdodo rẹ̀, yóò sì fi gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kún un fún yín pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.