Matiu 6:25
Matthew 6:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ?
Matthew 6:25 in English
Matthew 6:25 · Berean Standard Bible
Therefore I tell you, do not worry about your life, what you will eat or drink; or about your body, what you will wear. Is not life more than food, and the body more than clothes?
Context
23Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó! 24“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀. 25“Nítorí náà, mo wí fún yín, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nípa ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ ó jẹ àti èyí tí ẹ ó mu; tàbí nípa ara yín, ohun tí ẹ ó wọ̀. Ṣé ẹ̀mí kò ha ṣe pàtàkì ju oúnjẹ lọ tàbí ara ni kò ha ṣe pàtàkì ju aṣọ lọ? 26Ẹ wo àwọn ẹyẹ ojú ọrun; wọn kì í gbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kójọ sínú àká, síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? 27Ta ni nínú gbogbo yín nípa àníyàn ṣíṣe ti ó lè fi ìṣẹ́jú kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.