Native Bible

Matthew 6:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ojú ni fìtílà ara. Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀.

Matthew 6:22 in English

Matthew 6:22 · Berean Standard Bible

The eye is the lamp of the body. If your eyes are good,* your whole body will be full of light.

Context

20Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. 21Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú. 22“Ojú ni fìtílà ara. Bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀ kedere, gbogbo ara rẹ yóò jẹ́ kìkì ìmọ́lẹ̀. 23Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó! 24“Kò sì í ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀gá méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fi ara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sí. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.