Native Bible

Matthew 6:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ.

Matthew 6:19 in English

Matthew 6:19 · Berean Standard Bible

Do not store up for yourselves treasures on earth, where moth and rust * destroy, and where thieves break in and steal.

Context

17Ṣùgbọ́n nígbà tí ìwọ bá gbààwẹ̀, bu òróró sí orí rẹ, kí ó sì tún ojú rẹ ṣe dáradára. 18Kí ó má ṣe hàn sí ènìyàn pé ìwọ ń gbààwẹ̀, bí kò ṣe sì í Baba rẹ, ẹni tí ìwọ kò rí, àti pé, Baba rẹ tí ó rí ohun tí o ṣe ni ìkọ̀kọ̀, yóò san án fún ọ. 19“Má ṣe to àwọn ìṣúra jọ fún ara rẹ ní ayé yìí, níbi tí kòkòrò ti le jẹ ẹ́, tí ó sì ti le bàjẹ́ àti ibi tí àwọn olè lè fọ́ tí wọ́n yóò sì jí i lọ. 20Dípò bẹ́ẹ̀ to ìṣúra rẹ jọ sí ọ̀run, níbi ti kòkòrò àti ìpáàrà kò ti lè bà á jẹ́, àti ní ibi tí àwọn olè kò le fọ́ wọlé láti jí í lọ. 21Nítorí ibi tí ìṣúra yín bá wà níbẹ̀ náà ni ọkàn yín yóò wà pẹ̀lú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.