Matiu 5:37
Matthew 5:37 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi.
Matthew 5:37 in English
Matthew 5:37 · Berean Standard Bible
Simply let your ‘Yes’ be ‘Yes,’ and your ‘No,’ ‘No.’ Anything more comes from the evil one.*
Context
35Tàbí fi ayé búra, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ Ọlọ́run ni; tàbí Jerusalẹmu, nítorí olórí ìlú ọba ńlá ni. 36Má ṣe fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun ẹyọ kan di funfun tàbí di dúdú. 37Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àti bẹ́ẹ̀ kọ́ yín jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́, ohunkóhun tí ó ba ju ìwọ̀nyí lọ, wá láti ọ̀dọ̀ ẹni ibi. 38“Ẹ̀yin tí gbọ́ bí òfin tí wí pé, ‘Ojú fún ojú àti eyín fún eyín.’ 39Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ má ṣe tako ẹni ibi. Bí ẹnìkan bá gbá ọ lẹ́rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ẹ̀rẹ̀kẹ́ òsì sí olúwa rẹ̀ pẹ̀lú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.