Native Bible

Matthew 5:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run.

Matthew 5:20 in English

Matthew 5:20 · Berean Standard Bible

For I tell you that unless your righteousness exceeds that of the scribes and Pharisees, you will never enter the kingdom of heaven.

Context

18Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, àmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ. 19Ẹnikẹ́ni ti ó bá rú òfin tí ó tilẹ̀ kéré jùlọ, tí ó sì kọ́ ẹlòmíràn láti ṣe bẹ́ẹ̀, òun ni yóò kéré jùlọ ní ìjọba ọ̀run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe wọ́n, tí ó sì ń kọ́ wọn, ni yóò jẹ́ ẹni ńlá ní ìjọba ọ̀run. 20Nítorí náà ni mo ti wí fún yín pé àfi bí òdodo yín bá ju ti àwọn Farisi àti ti àwọn olùkọ́ òfin lọ, dájúdájú ẹ̀yin kì yóò le wọ ìjọba ọ̀run. 21“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí a ti wí fún àwọn ará ìgbàanì pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá pànìyàn yóò wà nínú ewu ìdájọ́.’ 22Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà,’ yóò fi ara hàn níwájú ìgbìmọ̀ àwọn àgbà Júù; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé, ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.