Matiu 5:16
Matthew 5:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo.
Matthew 5:16 in English
Matthew 5:16 · Berean Standard Bible
In the same way, let your light shine before men, that they may see your good deeds and glorify your Father in heaven.
Context
14“Ẹyin ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ìlú tí a tẹ̀dó sórí òkè kò lè fi ara sin. 15Bẹ́ẹ̀ ni a kì í tan fìtílà tán, kí a sì gbé e sí abẹ́ òsùwọ̀n; bí kò ṣe sí orí ọ̀pá fìtílà, a sì tan ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹni tí ń bẹ nínú ilé. 16Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín kí ó mọ́lẹ̀ níwájú ènìyàn, kí wọ́n lè máa rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run lógo. 17“Ẹ má ṣe rò pé, èmí wá láti pa òfin àwọn wòlíì run, èmi kò wá láti pa wọn rẹ́, bí kò ṣe láti mú wọn ṣẹ. 18Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, títí ọ̀run òun ayé yóò fi kọjá, àmì kínkínní tí a fi gègé ṣe kan kì yóò parẹ́ kúrò nínú gbogbo òfin tó wà nínú ìwé òfin títí gbogbo rẹ̀ yóò fi wá sí ìmúṣẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.