Native Bible

Matthew 3:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Jesu sì dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Johanu gbà, ó sì ṣe ìtẹ̀bọmi fún un.

Matthew 3:15 in English

Matthew 3:15 · Berean Standard Bible

“Let it be so now,” Jesus replied. “It is fitting for us to fulfill all righteousness in this way.” Then John permitted Him.

Context

13Nígbà náà ni Jesu ti Galili wá sí odò Jordani kí Johanu bá à lè ṣe ìtẹ̀bọmi fún un. 14Ṣùgbọ́n Johanu kò fẹ́ ṣe ìtẹ̀bọmi fún un, ó wí pé, “Ìwọ ni ìbá bamitiisi fún mi, ìwọ sì tọ̀ mí wá?” 15Jesu sì dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni Johanu gbà, ó sì ṣe ìtẹ̀bọmi fún un. 16Bí ó si tí ṣe ìtẹ̀bọmi fún Jesu tán, Ó jáde láti inú omi. Ní àkókò náà ọ̀run ṣí sílẹ̀ fún un, Ó sì rí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, ó sì bà lé e. 17Ohùn kan láti ọ̀run wá sì wí pé, “Èyí sì ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.