Native Bible

Matthew 28:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísinsin yìí, ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Galili síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò gbé rí i,’ wò ó, o ti sọ fún yin.”

Matthew 28:7 in English

Matthew 28:7 · Berean Standard Bible

Then go quickly and tell His disciples, ‘He has risen from the dead and is going ahead of you into Galilee. There you will see Him.’ See, I have told you.”

Context

5Nígbà náà ni angẹli náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 6Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí. 7Nísinsin yìí, ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Galili síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò gbé rí i,’ wò ó, o ti sọ fún yin.” 8Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìròyìn tí angẹli náà fi fún wọn. 9Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jesu pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà”, wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.