Native Bible

Matthew 27:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e.

Matthew 27:9 in English

Matthew 27:9 · Berean Standard Bible

Then what was spoken through Jeremiah the prophet was fulfilled: “They took the thirty pieces of silver, the price set on Him by the people of Israel,

Context

7Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀. 8Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní. 9Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e. 10Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ.” 11Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?” Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.