Matiu 27:6
Matthew 27:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.”
Matthew 27:6 in English
Matthew 27:6 · Berean Standard Bible
The chief priests picked up the pieces of silver and said, “It is unlawful to put this into the treasury, since it is blood money.”
Context
4Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”
Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!” 5Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso. 6Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” 7Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀. 8Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.