Matiu 27:41
Matthew 27:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà.
Matthew 27:41 in English
Matthew 27:41 · Berean Standard Bible
In the same way, the chief priests, scribes, and elders mocked Him, saying,
Context
39Àwọn tí ń kọjá lọ sì ń bú u. Wọ́n sì ń mi orí wọn pé: 40“Ìwọ tí yóò wó tẹmpili, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!” 41Bákan náà àwọn olórí àlùfáà pẹ̀lú àwọn akọ̀wé òfin àti àwọn àgbàgbà Júù sì fi í ṣe ẹlẹ́yà. 42Wọ́n kẹ́gàn rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Israẹli? Sọ̀kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsin yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́. 43Ó gba Ọlọ́run gbọ́, jẹ́ kí Ọlọ́run gbà á là ní ìsinsin yìí tí òun bá fẹ́ ẹ. Ǹjẹ́ òun kò wí pé, èmi ni Ọmọ Ọlọ́run?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.