Matiu 26:64
Matthew 26:64 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.”
Matthew 26:64 in English
Matthew 26:64 · Berean Standard Bible
“You have said it yourself,” Jesus answered. “But I say to all of you, from now on you will see the Son of Man sitting at the right hand of Power * and coming on the clouds of heaven.”*
Context
62Nígbà náà ni olórí àlùfáà sì dìde, ó wí fún Jesu pé, “Ẹ̀rí yìí ń kọ́? Ìwọ sọ bẹ́ẹ̀ tàbí ìwọ kò sọ bẹ́ẹ̀?” 63Ṣùgbọ́n Jesu dákẹ́ rọ́rọ́.
Nígbà náà ni olórí àlùfáà wí fún un pé, “Mo fi ọ́ bú ní orúkọ Ọlọ́run alààyè, kí ó sọ fún wa, bí ìwọ bá í ṣe Kristi Ọmọ Ọlọ́run.” 64Jesu sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ wí.” Ṣùgbọ́n mo wí fún gbogbo yín. “Ẹ̀yin yóò rí Ọmọ Ènìyàn ti yóò jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún alágbára, tí yóò sì máa bọ̀ wá láti inú ìkùùkuu.” 65Nígbà náà ni olórí àlùfáà fa aṣọ òun tìkára rẹ̀ ya. Ó sì kígbe pé, “Ọ̀rọ̀-òdì! Kí ni a tún ń wá ẹlẹ́rìí fún? Gbogbo yín ti gbọ́ ọ̀rọ̀-òdì rẹ̀. Kí ni ìdájọ́ yín?” 66Ki ni ẹ ti rò èyí sí.
Gbogbo wọn sì kígbe lọ́hùn kan pé, “Ó jẹ̀bi ikú!”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.