Matiu 26:55
Matthew 26:55 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Jesu wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Ǹjẹ́ èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹmpili, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà.
Matthew 26:55 in English
Matthew 26:55 · Berean Standard Bible
At that time Jesus said to the crowd, “Have you come out with swords and clubs to arrest Me as you would an outlaw? Every day I sat teaching in the temple courts,* and you did not arrest Me.
Context
53Ìwọ kò mọ̀ pé èmi lè béèrè lọ́wọ́ Baba mi kí ó fún mi ju légíónì angẹli méjìlá? Òun yóò sì fi wọ́n ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 54Ṣùgbọ́n bí mo bá ṣe eléyìí ọ̀nà wo ni a ó fi mú Ìwé Mímọ́ ṣẹ, èyí tí ó ti sọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ nísinsin yìí?” 55Nígbà náà ni Jesu wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Ǹjẹ́ èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹmpili, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà. 56Ṣùgbọ́n gbogbo wọ̀nyí ń ṣẹlẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a tì ẹnu àwọn wòlíì sọ, tí a kọ sínú Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.” Nígbà yìí gan an ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n sì sálọ. 57Àwọn tí ó mú Jesu fà á lọ sí ilé Kaiafa, olórí àlùfáà, níbi ti àwọn olùkọ́ òfin àti gbogbo àwọn àgbàgbà Júù péjọ sí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.