Matiu 26:24
Matthew 26:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.”
Matthew 26:24 in English
Matthew 26:24 · Berean Standard Bible
The Son of Man will go just as it is written about Him, but woe to that man by whom He is betrayed. It would be better for him if he had not been born.”
Context
22Ìbànújẹ́ sì bo ọkàn wọn nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí. Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí bi í pé, “Olúwa, èmi ni bí?” 23Jesu dáhùn pé, “Ẹni ti ó bá mi tọwọ́ bọ inú àwo, ni yóò fi mi hàn. 24Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀: ṣùgbọ́n ègbé ni fún ọkùnrin náà lọ́wọ́ ẹni tí a ó ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn! Ìbá kúkú sàn fún ẹni náà, bí a kò bá bí.” 25Judasi, ẹni tí ó fi í hàn pẹ̀lú béèrè pé, “Rabbi, èmi ni bí?”
Jesu sì dá a lóhùn pé, “Ìwọ wí i.” 26Bí wọ́n ti ń jẹun, Jesu sì mú ìwọ̀n àkàrà kékeré kan, lẹ́yìn tí ó ti gbàdúrà sí i, ó bù ú, Ó fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, Ó wí pé, “Gbà, jẹ; nítorí èyí ni ara mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.